Gómìnà Zamfara kò lágbára ní tòtọ́ọ́ lórí ọ̀rọ̀ ààbò- amòfin

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Gómìnà Zamfara kò lágbára ní tòtọ́ọ́ lórí ọ̀rọ̀ ààbò- amòfin
Published

Amofin Oyeyemi Balogun sọ pe otitọ ni ọrọ ti gomina ipinlẹ Zamfara governor pe oun ko lagbara to to lati paṣẹ fawon soja ati awọn agbofinro mii lati dẹkun ipaniyan to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa.

Nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Balogun ṣalaye wi pe fidihẹ lasan ni awọn gomina ipinlẹ lori ohun ti wọn le ṣe lori ọrọ eto aabo nipinlẹ wọn.

O ni awọn gomina dabi aja ti ko leyin lẹnu ti ko si tun lee gbo debi pe yoo bu eeyan jẹ, nitori gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto aabo pata wa labẹ aarẹ orilẹede Naijiria.