BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
"Àwa òbí ni a dá owó dọ́là fáwọn ajínigbé kí wọ́n tó tú àwọn àgùnbánirọ̀ ọmọ wa sílẹ̀, ọmọ mi kò sìnrúùlú mọ́ ní Imo"
Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria sọ pe awọn ọlọpaa pẹlu iranlọwọ awọn ẹṣọ eleto aabo mii ni wọn doola awọn agunbanirọ ogun naa.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Fídíò, 'A kò tíì ri ara bàlúù náà gan, awakọ̀ bàlúú yìí ni ì bá lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó - Gómìnà Lucky Aiyedatiwa, Duration 2,42
O ni pẹlu bi nnkan ṣe ri lagbegbe ti baluu na ja si, o fihan pe ko si ẹni to ye iṣẹlẹ ijamba naa.
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àgọ́ ara rẹ tí o bá lo òògùn Paracetamol lápọ̀jù, tí májèlé rẹ̀ sì wọlé sí ọ lára?
Gẹgẹ bi ajọ eleto ilera nilẹ Gẹẹsi ti wi, ti eeyan kan ba lo apọju oogun Paracetamol, o le se akoba nla fun Kindinrin ati ẹdọ foro rẹ.
Ohun tí a mọ̀ nípa bí odò ṣe gbé ọmọ bàbá kan náà mẹ́ta lọ
Maryam, ọmọ ọdun mejila; Umaru, ọmọ ọdun mẹwaa, ati Hanifa toun jẹ ọmọ ọdun mẹjọ ni awọn mẹtẹẹta ti odo gbe lọ lagbegbe Kuje.
Àlàyé lórí bí ìbejì ọmọ ìyá kan náà ṣe kú láàárín ọjọ́ méjì síra wọn, ohun gangan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn
Lẹyin ti Aidah kuro nile iwosan, to lọ si Nguru lati lọ daro iku ibeji rẹ, ọjọ Aiku to jẹ ọjọ meji lẹyin iku ibeji rẹ loun naa dagbere faye.
Wọ́n ti rí lára àfọ́kù bàlúù ológun NAF 931 tó já lọ́jọ́ Ajé
BBC News Yoruba wa nilu Igbokoda lati mọ nipa bi isẹlẹ naa se waye ati bi wọn yoo ti yọ awọn oku naa amọ titi di akoko yii, wọn ko tii ri awọn oku naa yọ.
Èrò bàálù tó gbé àrùn Ebola wọ Kenya kú, wọ́n ń wá èèyàn 28 tó farakínra pẹ̀lú rẹ̀
Minisita feto ilera nilẹ Kenya, Aden Duale lo sisọ loju ọrọ naa pẹlu alaye pe ọmọ orilẹede naa kan, to ti n gbe ni orilẹede Congo tẹlẹ lati ọdun meje sẹyin lo ko arun ọhun wọle.
Àlàyé lórí ìgbà mẹ́wàá tí bààlúù ológun tí já láàárín ọdún márùn-ún ní Naijiria
O kere tan, ijamba baaluu ologun to waye laaarin ọdun 2021 si 2026 yii to mẹwaa, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe wa fun awọn iṣẹlẹ naa lorilẹede Naijiria.
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkunrin tó kú sínú bààlúú tó ń bọ̀ sí ìlú Eko láti Kenya
Atẹjade ti wọn fi soju opo X wọn lọjọ keje oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ṣalaye pe, ṣadeede ni ọkunrin naa ko mọ ibi to wa mọ, ti ko si jọ pe o n mi mọ, ki ọkọ ofurufu naa too balẹ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, niluu Eko.
Ìtumọ̀ 'Èmi Ló Kàn' rèé, ọmọ Naijiria ní láti já ìjọba àwarawa gbà padà lọ́dún 2027
Niluu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Aarẹ BolaTinubu ti sọ pe ''Emi Lo Kan'' nigba to n ṣe ipolongo fun ibo aarẹ ọdun 2023.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Àwọn ọmọ ilẹ̀ Afirika ní láti máa sọ ìtàn ilẹ̀ wọn fúnra wọn sí i - Ọ̀dọ́mọdé òǹkọ̀tàn àti ayàwòrán, Duration 2,45
Ọdọmọde ayaworan naa sọ pe awọn ọmọ ilẹ Afirika lo le sọ itan ilẹ wọn gẹgẹ bi o ṣe ri gan an.
Àlàyé lórí i bí ẹ̀ṣọ́ Amọtẹkun, àjọ DSS àti àpapọ̀ ọmọ ogun ṣe gbẹ̀mí adarí ISWAP nílùú Owo l'Ondo
Ṣaaju iku rẹ, Ohida yii ni igbakeji Abu Ikrimah, ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu Uwais, to jẹ olori ISWAP ni aringbungbun Naijiria ki ọwọ ajọ DSS to tẹ ẹ lọdun 2023.
Seyi Makinde, Olubadan, sọ̀rọ̀ tuntun lórí àwọn àgùnbánirọ̀ Oyo tí wọ́n jí gbé ní Imo, àlàyé rèé
Gomina Makinde ṣọ pe ijọba Oyo ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ to yẹ lati ri awọn ọmọ naa gba pada.
Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Temi Nkem tó jáwé olúborí nínú ètò Big Brother Naija Season 11 pẹ̀lú ẹ̀bùn kàbìtì
Temitope Chigbue ti apetan orukọ rẹ n jẹ Temi, ẹni ọdun mọkanlelogun, fakọyọ ninu eto naa ti wọn pe ni ''Show Ya Sef.''
Ṣe ìwàásù nínú ọkọ̀ kó o rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ he, ìjọba ṣàgbékalẹ̀ òfin tuntun
Lọpọ igba, wọn maa n duro lẹyin awakọ, ti awọn miran si maa n rin lọ siwaju ati si ẹyin ninu bọọsi naa lati ṣiṣẹ ti wọn gba, bii kika Bibeli, sisọrọ Ọlọrun ati pipe awọn ẹlẹṣẹ lati ronu piwada.
Fídíò, Ìtàn ìgbésí ayé 'Bàbá', ìjàpá tó bá Aláàfin Oyo márùn-ún lògbà kó tóó jáde láyé, Duration 3,59
Oyo ilé ni wọn ti gbe Bàbá wa, ki i ṣe Oyo ode oni ti a mọ si Oyo Atiba.
Ṣé lóòótọ́ ni Teniola àti Tiwa Savage yóò wàákò nínú ẹ̀ṣẹ́ kíkàn láti gba ₦1.5bn? Ohun tí a mọ̀ rèé
Teni lo ke pe Tiwa Savage wi pe oun ṣetan lati ba a wọya ija awọn gbajumọ ati pe to ba to bẹẹ, ko da oun lohun.
Ohun tí ìṣèjọba Tinubu ní í ṣe pẹ̀lú ikú ìyá mi - Amaechi
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2026 ti a wa yii ni mama Amaechi, Arabinrin Ezinne Amaechi jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89).
Àwọn ọmọ Nàìjíríà 105 mí-ìn tún dé láti South Africa, wọ́n ní ọ̀pọ̀ ló ti kú s'ájò
Tẹ o ba gbagbe, awọn ọmọ Naijiria kan naa pada si orilẹede yii lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹsan-an ọdun yii, 105 ni awọn naa niye.
Igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Naijiria ṣáájú àwọn agbófinró ní Imo láti wá àgùnbánirọ̀ 20 àtàwọn èrò mí-ìn tí ajínigbé gbé lọ
Aṣẹ IGP Olatunji lo gbe DIG Shehu Nadada pẹlu awọn kọmiṣanna ọlọpaa meji mi-in de Imo, lati dari ọna ti wọn yoo fi ri awọn to wa ni ahamọ ajinigbe naa gba pada.
Agbésùnmọ̀mì tún pa àgbẹ̀ 15 sínú oko, mẹ́ta di àwátì
Iṣẹlẹ yii waye nijọba ibilẹ Marte, ipinlẹ Borno, lasiko tawọn agbẹ naa wa ninu oko wọn lọwọ irọlẹ, lagbegbe Ala ati Musune.
Igun ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ wo ló bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta? Àlàyé rèé
Iyanṣelodi naa bẹrẹ lati ọjọ keji, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii ti yoo si pari ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ẹ jẹ́ kí n padà sí sinimá ṣiṣe, ó hàn pé mí ò kí ń ṣe ẹlẹ́ṣẹ́ – Nkechi Blessing sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jàn án mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́
Ija naa ni akọkọ iru rẹ fun awọn gbajumọ obinrin ni Naijiria, eyii ti ileeṣẹ Balmoral Promotions ṣe agbatẹru rẹ.
Olu Jacobs, àgbà òṣèré wọ káà ilẹ̀ sún l'Ekoo
Ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kejì oṣù Kẹwàá ọdún 2026 yìí ni wọn sìnkú Olú Jacobs si itẹ òkú Ikoyi, niluu Eko.
Kà nípa kòkúmọ́ obìnrin tí wọ́n gún lábẹ́rẹ́ ikú nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àmọ́ tí kò kú
Ikọ agbẹjọro Christa Pike, niluu Tennessee pe ẹjọ pajawiri pe ki wọn da iku rẹ duro lasiko ti wọn n gbiyanju lati gbẹmi rẹ lọwọ pe ọdaran ọhun ti daku bo tilẹ jẹ pe o ṣi n mi, to si n hanrun.
Ńjẹ́ o mọ̀ pé àdó olóró ti bú rí nítòsí ààrẹ lásìkò àyàjọ́ òmìnira ní Nàìjíríà? Ohun mánigbàgbé márun tó wáyé rí lọ́jọ́ àyájọ́ òmìnira
Ọmọọbabinrin Alexandra ti Kent lo ṣoju Ọbabinrin Elizabeth keji nibi ayẹyẹ ọhun, o si ti de si Naijiria lati ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsa, ọdun naa.
Wo ohun tí ìjọba fẹ́ fi $1.5bn tí wọ́n fẹ́ yá ní ilé ìfowópamọ́ àgbáyé ṣe
Laaarin ọdun mẹta bayii, gbese Naijiria ti lekun ni ilọpo meji. N87.38trn ni gbese Naijiria ni oṣu Kẹfa ọdun 2023 ṣugbọn to ti fo wọ N166.79trnni ipari oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà, gbajúmọ̀ akọ̀ròyìn yóò di ọba alayé ní Uganda
Oniruuru ariyanjiyan lo ti n waye nipa bo ṣe jẹ pe ọkunrin na ani wọn yan fun ipo ọba ilu Tooro yii.
Nàìjíríà kéde orúkọ àwọn ọmọ Naìjíríà mẹ́ta tí wọ́n tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣekúpa ní South Africa, pè fún ìwádìí
Ọrọ yii ti n pa okuta si ajọṣepọ laarin orilẹede Naijiria ati South Africa.
Wo Olamiju ọmọ Alao-Akala, Iyabo ọmọ Obasanjo, Adamu ọmọ Atiku, Yusuf ọmọ Buhari àtàwọn ọmọ gbajumọ olóṣèlú tó ń díje ibò ọdún 2027
Lara wọn lawọn ọmọ Aarẹ ati igbakeji tẹlẹ, gomina tẹlẹ atawọn eekan oloṣelu miran










































































