Wọ́n ti rí lára àfọ́kù bàlúù ológun NAF 931 tó já lọ́jọ́ Ajé

Aworan afọku baluu naa ati awọn eeyan to duro sibẹ pẹlu gomina Ayedatiwa ati olori ọwọ ọmọogun ojuomi to wa ni Igbọkọda
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Wọn ti ri lara afọku baluu Ologun to j ani ilu Igbokoda ni ipinlẹ Ondo lọjọ Aje.

Ọga Ologun ọwọ ileeṣẹ ọmọogun oriomi to wa lagbegbe Igbọkọda lo sọ eyi lasiko ti gomina ipinlẹ Ondo, Ayedatiwa ṣe abẹwo si ibi ti baluu naa ja si ni Ọjọru.

Akitiyan ṣi n lọ lati ri afọku baluu naa atawọn oku awọn eeyan to ku ninu rẹ.

Baluu na wọ inu ira to wa nibi odo to ja si eleyi ti awọn alaṣẹ n ṣalaye pe o mu ki akitiyan lati ri afọku rẹ ati oku awọn eeyan to ku ninu ijamba le pupọ.

Iṣẹ awari awọn afọku baluu naa ati oku awọn to wa ninu rẹ ṣi n lọ lọw ninu ira odo ti baluu naa ja si ni Igbọkọda.

Baaluu ileeṣẹ ologun NAF 931 to jabọ n'Igbokoda, ipinlẹ Ondo lawọn alaṣẹ ileeṣẹ Ologun ofurufu lorilẹede Naijiria ṣalaye pe o n tiilu Benin lọ si ilu Eko fun iṣẹ Ologun kan ti wọn ko sọ sit ani pato.

Eeyan marundinlọgbọn ni wọn sọ pe o wa ninu baluu naa nigba to j ani owurọ ọjọ Aje.

Kí ló dé tó ṣe nira láti rí àjákù bàálù àti òkú àwọn ológun tó kú nínú bàálù tó já ní Igbokoda lẹ́yìn ọjọ́ méjì?

Ọkọ Katakata n wọ inu odo lọ laarin awọn ọkọ oju omi to wa lori odo naa, lati yọ oku awn eeyan to ja sinu baalu

Lẹyin ọjọ meji ti baalu ologun kan ja nilu Igbokoda nipinlẹ Ondo, wọn ko tii ri ajaku baalu naa ati oku awọn eeyan mẹẹdọgbọn to ba baalu naa rin yọ.

Ọsan ọjọ Aje ni baalu ologun to n bọ lati ilu Benin wa silu Eko ja lulẹ sinu odo nla kan ni ipinlẹ Ondo naa, to si pa gbogbo ero mẹẹdọgbọn to wa ninu rẹ.

BBC News Yoruba wa nilu Igbokoda lati mọ nipa bi isẹlẹ naa se waye ati bi wọn yoo ti yọ awọn oku naa amọ titi di akoko yii, wọn ko tii ri awọn oku naa yọ.

BBC wa se iwadi idi ti eyi fi ri bẹẹ, ti a si ri pe inu irà nla, ti omi kun ori rẹ ni baalu naa ja si eyi to n se idiwọ nla fawọn osisẹ adoola ẹmi lati sisẹ wọn.

Ọkọ oju omi la wọ de ibi ti a ti gbọ ariwo nla nigba ti baalu naa ja amọ baalu naa ti wọ inu ira lọ - Awọn Onmuwẹ ni Igbokoda

BBC News Yoruba tun bawọn araalu ni Igbokoda ti wọn jẹ onmuwẹ sọrọ nipa aayan wọn lati yọ awọn eeyan yii.

Awọn Onmuwẹ naa salaye pe lootọ ni awọn tete sare lọ ibi ti isẹlẹ naa ti waye amọ o nira pupọ fun wọn lati tete de ibi isẹlẹ naa.

Awọn naa fidi rẹ mulẹ pe agbegbe naa to nira lati wọ tori igi nla to yii ibẹ ka se idiwọ pupọ fun wọn lati doola awọn eeyan to wa ninu baalu naa.

Wọn ni ọkọ oju omi lawọn wọ de agbegbe naa lati mọ ohun to sẹlẹ nigba ti awọn gbọ ariwo nla naa.

Wọn ni inu ira ni baalu naa ja si, to si rin sinu odo ira naa.

Awọn osisẹ eleto pajawiri sọ̀rọ̀ nipa isoro ti wọn koju lati yọ ajaku baalu

Nigba ti ikọ iroyin BBC News Yoruba bawọn osisẹ ajọ eleto pajawiri nipinlẹ Ondo, SEMA sọrọ, wọn fidi rẹ mulẹ pe inu Ira ti baalu yii ja si lo tun mu ko nira fun awọn atawọn eeyan ilu naa lati doola ẹmi awọn ero inu baalu naa.

Baalu naa tii se ATR – 42, ti nọmba rẹ si jẹ NGR 931 lo wọ inu ira lọ patapata, to si nira lati ri ajaku ati ero inu rẹ gbe jade.

Wọn fikun pe awọn igi nla ati omi to kun fun ẹrọfọ lo sediwọ fun isẹ idoola ẹmi ti wọn n se nibi ti isẹlẹ ijamba baalu naa ti waye.

Idi si ree to mu ko nira lati se awari apoti dudu (Black Boxes) to maa slaaye idi ti ijamba baalu naa se waye.

Koda, oniruuru awọn ẹrọ igbalode to fi mọ ẹrọ katakata ni wọn n lo lati wọ inu ira naa.

Ọlọpaa naa salaye idiwọ ti wọn n ni lati yọ oku awọn ologun to ku

Bakan naa ni Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Felix Ohagwu, se apejuwe agbegbe ti isẹlẹ naa ti waye gẹgẹ bii eyi to jẹ ipenija nla fun wọn lati doola ẹmi.

Koda, o fikun pe kawọn to le de ibi isẹlẹ naa ko dẹrun rara, koda, ọkọ oju lo ni awọn lo lati de ibẹ.

Amọ o wa fi ọwọ idaniloju sọya pe isẹ awari awọn oku naa ati ajaku baalu si n lọ lọwọ, ti wọn si ti beere fun oniruuru ẹrọ igbalode lati se atilẹyin fun isẹ ti wọn n se.

Bakan naa lo ni awọn n reti atilẹyin ajọ eleto iranwọ pajawiri ti NEMA ati SEMA atawọn ajọ miran lati pese awọn ẹrọ nlanla to le yọ ajaku baalu ọhun kuro ninu ira to ri si.

Kọmisana feto ilera seleri pe awọn ohun eelo ti wọn nilo lati yọ awọn oku ati ajaku baalu yoo de ibẹ lonii

Kọmisana feto ilera nipinlẹ Ondo, Dokita Banji Ajaka naa se ipade awọn akọroyin nipa isẹlẹ yii.

O fidi rẹ mulẹ pe oun ati ọga ologun to wa nilu naa lawọn dijọ wa ninu igbo yii lati mojuto eto sise awari awọn oku ati baalu naa.

O ni awọn ọkọ anbulansi lawọn ile iwosan ijọba to wa lawọn ijọba ibilẹ Ilaje ati Okitipupa lawọn ti fi ransẹ sibi ti isẹlẹ naa ti waye.

Ajaka wa fidi rẹ mulẹ pe oun wa nibi isẹlẹ naa titi di aago mọkanla alẹ pẹlu awọn onmuwẹ labẹle lati mọ bi wọn yoo se ri awọn oku naa.

O wa koro oju si awọn ofege iroyin tawọn eeyan kan n pin kiri nipa isẹlẹ naa, to si sekilọ pe ki wọn dẹkun pinpin awọn fidio to jẹ irọ pọnbele nipa isẹlẹ naa.

Bakan naa lo fi ọwọ sọya pe awọn yoo ko awọn ohun eelo to yẹ lọ sibudo isẹlẹ naa ni aarọ oni.

Baluu NAF 931 wa ni papakọ ofurufu

Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bàlúù ọmogun ATR 42-500 tó já l'Ondo tó fi mọ́ ìgbà tí Naijiria rà á

NAF 931 ni nọmba idanimọ baluu ileeṣẹ ọmọogun ofurufu orilẹede Naijiria to ja nitosi ibudo awọn ọmọogun oju omi to wa niluu Igbọkọda nijọba ibilẹ Alaje nipinlẹ Ondo lọjọ Aje ọjọ karun un oṣu Kẹwaa yii.

Eeyan mejilelọgbọn lo wa ninu baalu ileeṣẹ ọmogun naa to ja sinu ira ni Igbokoda.

Baluu to ja yii jẹ ọkọ ofurufu ileeṣẹ ọmogun ofurufu orilẹede Naijiria eyi to ni nọmba ATR 42 ni iru rẹ.

Ileeṣẹ kan to jẹ ti orilẹede France ati Italy lo ṣe baluu ọmogun ofurufu ATR 42 to ja naa lọjọ Aje l'Ondo.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn bẹrẹ sii ṣe irufẹ baluu ATR 42-500 yii lati ọdun 1995 si 2006, ọpọ orilẹede lo si n ra a lati maa lo.

Irufẹ baluu yii le gbe aadọta eeyan rinrin ajo, amọ, iwadii fi idi rẹ mulẹ pe lọdun 2010 ni orilẹede Naijiria ra baluu to ja yii.

Baluu yii jẹ ọkọ ofurufu ATR 42-500 MP tawọn ọmogun maa n lo lati maa ṣe amojuto ohun to n ṣẹlẹ kaakiri lori eto aabo ori omi.

Eyi ni wọn fi pe e ni ATR 42-500 tori ohun ni wọn maa n lo lati mojuto agbegbe ti omi ba wa.

Amọ, iwadii fi han pe oriṣiiriṣii nnkan lawọn ologun ti lo baluu naa fun.

Baluu yii ni wọn fi ko awọn akẹkọọbinrin ileeṣẹ ọmogun ofurufu loṣu Kẹrin ọdun 2025.

Ohun naa ni wọn maa fi gbe awọn akẹkọọ ile ẹkọ ọmogun kaakiri orilẹede Naijiria fun iwọle igbẹkọ tuntun loṣu Kẹsan an ọdun yii.

Ileeṣẹ ọmogun Naijiria ra baluu ATR 42-500 lati maa gbogun ti iwa ọdaran lori omi pẹlu ajọṣepọ ajọ NIMASA.

Wọn ṣe ifihan baluu yii ni olu ileeṣẹ ọmogun ofurufu to wa niluu Eko lọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2014.

Ajọ NIMASA ṣẹṣẹ ra oriṣiiriṣii satalaiti lati le maa fi gbogun ti awọn ọdaran ori omi pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ọmogun ofurufu ati ọmogun ori omi Naijiria.

Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi si n gbiyanju lati ṣawari awọn to wa ninu baluu ọhun.

Ọkunrin kan to wa aṣọ olomi buluu n wọ ilu baluu pẹlu baagi lọwọ

Gbogbo àwọn èèyàn 32 tó wà nínú bàlúù iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà tó já l'Ondo ló kú, Ààrẹ Tinubu ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ẹbí wọn

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi awọn eeyan marundinlọgbọn ati oṣiṣẹ baluu naa meje to ku ninu ijamba ọkọ baluu to ja n agbegbe ilu Igbọkọda ni ipinlẹ Ondo lọjọ Aje.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun aarẹ,Bayọ Ọnanuga fi sita nirọlẹ Ọjọ Aje, Aarẹ Tinubu ni ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria, Sunday Kelvin Aneke ti fi ẹkunrẹrẹ iroyin ijamba naa to oun leti, oun si ti ni ki iwadi to rinlẹ o bẹrẹ nipa ohun to ṣokunfa ijamba naa 'lati le dena irufẹ rẹ lọjọ iwaju'.

"Akoko ibanujẹnla gba a niyi fun awọn ọmọogun wa ati fun gbogbo orilẹede yii lapapọ. Awọn ologun ofurufu wa fi ẹmi wọn lelẹ lojoojumọ lati daabo bo orilẹede Naijiria. A ko ni gbagbe ifẹmiaraẹni rubọ wọn."

Bakan naa lo gbadura fun awọn to ku naa ki Ọlọrun le tu awọn ẹbi wọn ninu.

Àkànṣe iṣẹ́ ológun ni bàlúú tó já pẹ̀lú èèyàn 32 l'Ondo ń gbéra láti Benin lọ ṣe l'Eko – Iléeṣẹ́ ọmọogun ofúrufú Nàìjíríà

Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria ni oun ti bẹrẹ eto wiwa ati didoola awọn eeyan to wa ninu baluu ologun to ja ni agbegbe Igbọkọda ni ipinlẹ Ondo, lowurọ ọjọ Aje.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọmọogun ofurufu, Ọgagun Ehimen Ejodame fi sita, o ni iṣẹ aṣayan kan ni baluu naa gbera nilu Benin lati lọ ṣe nilu Eko ti ajalu ijamba naa fi waye.

Ọgagun Ehimen Ejodamen tun ṣalaye siwaju sii ninu atẹjade naa pe igbesẹ wiwa awọn eeyan to wa ninu baluu naa ti bẹrẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ajọ ijọba gbogbo to yẹ.

Lowurọ ọjọ aje oni, ọjọ karun-un oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni iroyin jade pe ọkọ baluu kan ti ja lorilẹede Naijiria.

Ohun ti a mọ nipa iṣẹlẹ ijamba baluu naa ree.

Owurọ ọjọ Aje ni baluu naa gbera ni Ilu Benin to si n lọ si ilu Eko pẹlu eeyan mejilelọgbọn ninu rẹ. Marun ninu wọn jẹ awọn awakọ ati oṣiṣẹ baluu naa ti awọn marundinlọgbọn yoku jẹ ero to ko.

Nnkan bi agogo mẹsan kọja iṣẹju mẹtala ni atọna rẹ sọnu loju ofurufu ti ibudo atọna baluu ko si rii kan simọ.

Ko pẹ pupọ si asiko yii ni iroyin jade pe baluu naa ti ja lulẹ nitosi ibudo awọn ọmọogun ojuomi to wa ni ilu igbọkọda ni ipinlẹ Ondo

Alaye ti minisita fun irinna ofurufu, Festus Keyamo ṣe ni pe nọmba idanimọ baluu naa ni NGR 931 tabi NAF 931, Ẹya baluu ATR-42-500MP Surveyor ni baluu naa.

Iwadii ti a ṣe fihan pe irufẹ awọn baluu yii jẹ ẹlẹnjini meji ti wọn maa fi n ṣe amojuto ati idaabobo awọn etido atieti omi gbogbo,

Awọn ọmọogun oju omi ati araalu ṣi nwa awọn eeyan to wa ninu rẹ lẹyin ti wọn ṣawari ibi ti baluu naa ja si

Lọwọ ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ ni awọn iroyin nipa ijamba naa ṣi n jẹyọ lẹyọ ẹyọ ni ati pe iwadi nlọ lọwọ.