Rwanda Genocide: Ó fẹ́ gba ẹ̀san ṣùgbọ́n ó padà dáríjì í

Àkọlé fídíò, 'Celestine fa adá yọ, ó sì gé orí ọmọ mi méjì'
Published

Ọjọ buruku eṣu gbomimu lọjọ naa lorílẹ̀-èdè èdè Rwanda.

Asiko yii ni ìrántí ọdún márùn-dínlọ́gbọ́n ti ìpànìyàn ẹlẹ́yàmẹ̀yà wáyé lórílẹ̀-èdè náà.

Arábínrin Anne Marie jẹ ọkan lara awọn ti ẹmi rẹ ko ba lọ si i. Ẹmi rẹ ko lọ si i ṣugbọn ojoojumọ lo fi n sọkun awọn ọmọ rẹ meji ti aldugbo rẹ Celestine pa lasiko ipaniyan lẹyamẹya ọhun.