World War III: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa awuyewuye tó ń wáyé láàárín India àti China

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ariwo World war 3 lawọn eeyan n pa bayii lori ayelujara lẹyin awuyewuye to waye laarin ilẹ India ati China lori ala ilẹ Himalayas, eyi to ti mu ẹmi awọn eeyan kan lọ.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa iṣẹlẹ naa ree.
Ki ni hun to ṣẹlẹ gan?
Ko din ni ogun lara awọn ọmọ ogun ilẹ India to jẹ Ọlọrun nipe ninu ikọlu to waye ni erekusu Galwan, ni agbegbe Ladakh.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ṣaaju ni China ti fẹsun kan India pe awọn ọmọ ogun rẹ rekọja ala wọn nigba meji ọtọtọ, ati pe wọn tun ṣakọlu si ẹgbẹgun oun.
Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeji ni ko si ninu ọmọ ogun wọn to yi ibọn, ilẹ India sọ pe ̣ ọwọ lasan, okuta, irin ati igi ni awọn awọn ọmọ ogun rẹ fi ja ija naa.
Lẹyin ti China sọ pe oun ti padanu lara awọn ọmọ ogun ohun ni awọn ọgagun lati orilẹ-ede meji naa pe ipade alaafia.
Ki lo fa ṣababi ija naa?

Oríṣun àwòrán, Press information bureau
O ti to nnkan bi ọdun diẹ sẹyin ti fa ki n fa ti n waye laarin orilẹ-ede meji ọhun nitori ilẹ kan ti awọn eeyan ki n gbe.
Ṣugbọn wahala bẹ silẹ lẹyin ti India ṣe opopona si agbegbe Ladakh, lẹba ilẹ kan naa to pin awọn mejeji ti wọn n ja si.Igbesẹ ọhun bi China ninu to bẹ ti oun naa fi lọ kọ ile kan sẹba ọna ti India ṣe, eyi to mu ki orilẹ-ede meji ọhun ko ọmọ ogun lọ sojuko naa.
Ewu n bẹ loko Longẹ

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn orilẹ-ede mejeji sọ pe ilẹ naa ṣe pataki si wọn nipa ọrọ aje ati eto abo.
Ewu to wa ninu fa ki n fa yii ni pe i awọn mejeji ba kọ lati pari ọrọ naa ni itubi inubi, o le da ogun silẹ lagbegbe ọhun.
Lati nnkan bi ọjọ diẹ sẹyin ni awọn ọgagun lati orile¬-ede meji naa ti n ṣepade lati yanju awọ yii, ṣugbọn igbiyanju lati pari iru awọ bayii latẹyinwa ko so eso rere.
Ọdun 1962 ni ogun ti waye gbẹyin laarin ilẹ mejeji, ṣugbọn ajẹkunniya ni India jẹ lọwọ China lọdun naa lọhun.
























