Community Policing: Àgbẹ́kalẹ̀ ọlọ́pàá agbègbè sí agbègbè ni ọ̀nà àbáyọ sí ìwá ọ̀daràn

Igbakeji ọga agba ajọ ọlọpaa to n mojuto ẹkun kọkanla, Lẹyẹ Oyebade ti tẹpẹlẹ mọn pataki ṣiṣe agbekale ọlọpaa agbegbe si agbegbe lati le dẹkun iwa ọdaran ati iwa ibaje jakejado orilẹede yii.Oyebade sọ ọrọ naa di mimọ nibi akanṣe abewo ifinimọle to waye l'Ọjọru ni olu ile iṣẹ ajọ ọlọpaa to kale si agbegbe ẹlẹyẹle nilu Ibadan.Ọga ọlọpaa naa ṣe alaye wi pe iwa ọdaran ati ibajẹ to n waye ni adugbo kọọkan yatọ sira wọn, nitori naa lo si fi ṣe pataki fun adugbo kọọkan lati ni awọn ọlọpaa to n gbe ni adugbo naa, nitori wi pe ọdẹ ile lo mọ ẹranko ile dẹ.

Ọyebade parọwa si awọn eeyan ilu lati maa gbe ninu irẹpọ nitori pe agbajọwọ la fi n sọya.O kesi awọn fulani darandaran, awọn ẹgbẹ awakọ, awọn oni karakata ati awọn adari ilu lati yago fun ohunkohun ti o le da rugudu silẹ ni agbegbe wọn.O fi kun ọrọ rẹ wi pe agbekale ọlọpaa agbegbe si agbegbe wa ni ibamu pẹluu erongba ọga agba ajọ ọlọpaa lorilẹede yii, Adamu Mohammed lati rii daju wi pe alafia jọba jakejado.

Oyebade ṣe ileri wi pe ajọ ọlọpa ko ni tẹti ninu ojuṣe rẹ lati maa fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn eeyan awujọ ki iwa ọdaran le afisẹhin ti eegun n fi'ṣọ. Lara awọn eeyan pataki ti o pejupesẹ sibi akanṣẹ eto naa ni awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ, awọn Ọba alade ati loyeloye, ẹgbẹ awọn fulani darandaran, ẹgbẹ awọn awakọ ati awọn adari agbegbe si agbegbe.




















