Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC tọ́wọ bọ̀wé àdéhùn, buwọ́lu N70,000 náírà gẹ́gẹ́ bí owó ọkọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́

Aarẹ Bola Tinubu ati alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC, Joe Ajaero
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lojuna lati mu igbe aye idẹrun ba awọn oṣiṣẹ ijọba kaakiri ilẹ Naijiria, ijọba apapọ ti tọwọ bọwe adehun tuntun pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC.

Bo tilẹ jẹ pe oniruuru ijiroro lo waye laaarin awọn aṣoju ijọba ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, sibẹ, gbogbo wọn lo panupọ lati fẹnuko lori adehun tuntun.

Nibi ipade ti awọn alakoso NLC ati ijọba apapọ ṣe lọjọ kejilelogun, ati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, ni wọn ti buwọlu ẹgbẹrun lọna aadọrin naira gẹgẹ bi owo iranwọ ọkọ wiwọ fun awọn oṣiṣẹ.

Ajọ NLC lo sọrọ nipa adojukọ awọn oṣiṣẹ pẹlu bi owo ọja ṣe lọ soke, owo oṣu tuntun awọn oṣiṣẹ, owo epo to lọ soke, to fi mọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ.

Ọmọwe Muhammad Maigari Dingyadi, to jẹ minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ lo buwọ lu iwe adehun naa pẹlu NLC lorukọ ijọba apapọ.

Timi Yakubu, alakoso eto iṣuna; Ọmọwe Garba Abdul S. U., akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ oṣiṣẹ lori ṣoju ijọba apapọ; nigba ti aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero ati akọwe agba fun ajọ JNPSNC, Olowoyo Gbenga, wa nibi ipade adehun tuntun naa pẹlu.

Ki ni wọn fẹnuko le lori?

Nibi ipade naa, ijọba apapọ yoo bẹrẹ sii san ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun gbogbo oṣiṣẹ patapata fun oṣu mẹfa gbako, ati pe inu oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni yoo bẹrẹ.

Ijọba tun buwọ lu owo ajẹmọnu, eyi to bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Karun-un, ọdun 2026, nigba ti owo ajẹẹlẹ yoo bẹrẹ ni sisan lati ibẹrẹ oṣu Kọkanla, ati pe oṣu mẹta-mẹta ni ijọba yoo maa san an.

Ni afikun, ijọba sọ pe ohun yoo san owo ajẹmọnu oṣu mọkandinlogun fun awọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera, eyi ti wọn yoo san fun oṣu mẹyta gbako, bẹrẹ lati oṣu Kejila, ọdun 2026.

Lori afikun owo oṣu tuntun, ijọba apapọ sọ pe wọn yoo ṣagbekalẹ igbimọ to n ri si ijiroro owo oṣu, ti wọn yoo si bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.