INEC lóun yóò wádìí àwòrán àwọn olùdìbò táwọn ọmọ Naijiria sọ pé AI ni lójú òpó rẹ̀

Ọjọgbọn Joash Amupitan, Alaga ajọ INEC. O wọ agbada funfun to ni awọ ẹrupẹ ilẹ, o de fila alawọ kan naa, bẹẹ lo mu ẹrọ gbohun-gbohun dani bo ṣe n sọrọ lọwọ.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi ariwo ṣe sọ lori ayelujara lọsẹ yii, ti awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si i tọka aworan awọn oludibo ti wọn ni ẹrọ AI ni wọn fi ṣe e loju opo ajọ eleto idibo ilẹ wa; INEC, ajọ naa ti ni oun yoo wadii ohun to ṣẹlẹ.

Agbẹnusọ INEC, Mohammed Kudu Haruna, lo fidi ẹ mulẹ pe awọn yoo wadii finni-finni nipa ohun tawọn eeyan pe ni AI naa.

Bakan naa lawọn eeyan kan tun tọka pe awọn orukọ kan ko si ninu eyi ti INEC gbe jade, bẹẹ lawọn kan sọ pe ẹẹmeji lo gbe orukọ awọn jade.

Si aroye mejeeji yii, INEC ko ti i fesi kankan lasiko ti a n kọ iroyin yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje ọsẹ yii ni INEC fi atẹjade orukọ ori ayelujara iṣi akọkọ naa lede.

Ṣe loootọ ni pe ẹrọ AI ni wọn fi ṣe aworan awọn oludibo naa?

Gẹgẹ bi BBC ṣe yẹ oju opo ayelujara ajọ INEC wo, a ri orukọ ati aworan awọn oludibo loootọ.

Amọ a ko le fidi ẹ mulẹ pe ẹrọ AI ni wọn fi gbe e jade.

Ninu ọrọ ti Alukoro ajọ naa, Mohammed Kudu Haruna, ba BBC sọ lo ti ni awọn yoo tuṣu ọrọ naa de isalẹ ikoko.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Fun ẹyin tẹ ẹ ni ẹ ri AI, mo maa lọ ba awọn to wa lẹka imọ ẹrọ, ma a sọ ohun ti ẹ wi fun wọn.

"Lakọkọ na, a gbọdọ ri I daju pe loootọ, aworan AI lo wa ni akọsilẹ wa, lẹẹkeji, wọn a sọ fun mi biyẹn ṣe ṣẹlẹ ki n too waa jábọ̀ fun yin."

Bẹẹ ni Alukoro ajọ eleto idibo INEC naa wi.

Ninu atẹjade ti INEC fi sita lọjọ Iṣẹgun ana, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2026, o ṣalaye pe akọsilẹ orukọ awọn oludibo toun fi sita lọjọ Aje, jẹ ọkan naa pẹlu eyi toun ti fi sita lawọn ibudo iforukọsilẹ kaakiri Naijiria.

Eyi waye laaarin ọjọ kẹsan-an si ikẹẹdogun oṣu Kẹwaa 2026.

Ajọ naa sọ pe awọn ibeere kan jẹ jade nipa awọn akọsilẹ iforukọsilẹ naa, oun si kede rẹ fun ayẹwo si i.

INEC sọ pe o ṣe pataki lati mọ pe eyi kọ ni opin atẹjade orukọ naa, bi ko ṣe pe kawọn eeyan le fi tọka awọn aleebu to ba wa nibẹ fun atunṣe.

"A dupẹ lọwọ awọn alawofin to fi eyi setigbọọ gbogbo eeyan, iru rẹ maa n ṣe iranlọwọ fun ododo ati deede eto iforukósilẹ ni."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade INEC ka.

"Wọn yoo ṣe ayẹwo to yẹ bi wọn ṣe wi, ṣaaju ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kejila ọdun 2026 yii ti opin yoo de ba iforukọsilẹ awọn oludibo.

Ki ni ofin sọ nipa iwe orukọ awọn oludibo?

Abala 19(5) ofin eleto idibo ilẹ wa sọ pe:

"Oṣiṣẹ ajọ naa to ba kuna lati fi orukọ oludibo sita bo ṣe yẹ labẹ ofin kin-in-ni, ti ṣẹ si ofin.

Ofin naa sọ pe owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (100,000 naira) ni ijiya rẹ bi oṣiṣẹ naa ba jẹbi.

Tabi ko lọ si ẹwọn oṣu mẹfa, o si le sanwo itanran ko tun ṣẹwọn pẹlu.

Ofin sọ pe:

"Ko gbọdọ ju aadọrun-un ọjọ (90 days) lọ si idibo apapọ, ti ajọ eleto idibo yoo fi ya ọjọ meje sọtọ ti yoo fi orukọ awọn oludibo lede fun ijọba ibilẹ kọọkan, ti agbegbe tabi wọọdu.

"Ti wọn yoo gbe e jade fawọn araalu lati wo o finni-finni. Wọn yoo si fi si gbogbo agbegbe iforukọsilẹ, ati loju opo ayelujara wọn, tabi opo mi-in ti wọn gbe kalẹ fun eyi."